Iseda Oro-Oruko, Eto Iselu Abinbi Ati Ti Ode-Oni – SS3 Yoruba Lesson Note (Second Term)
Download this term · ₦1,000Lesson note at a glance
- Subject
- Yoruba
- Class
- SS3
- Term
- Second Term
- Topic
- Iseda Oro-Oruko, Eto Iselu Abinbi Ati Ti Ode-Oni
- Order
- Topic 4 of 5 this term
- Reading time
- 7 min
Iseda oro-oruko ni siseda oro-oruko lati ara oro-oruko tabi oro-ise nipa afomo lilo. Awon ona ti a n gba seda re ni afomo ibere, afomo aarin, apetunpe kikun, apetunpe elebe, akanpo oro-oruko ati isunki odidi gbolohun. Apeere ni a + yo = ayo ati a + lo = alo.
Ete eko
Ni opin eko yii, awon akeko yoo le:
- salaye kini iseda oro-oruko;
- daruko awon ona ti a n gba seda oro-oruko;
- seda oro-oruko nipa lilo afomo ibere;
- salaye ipa ti baale, iyaale, omokunrin ile, obinrin ile, omo osu ile ati omobinrin ile n ko ninu eto iselu abinibi;
- salaye bi eto iselu ode-oni se yato si ti aye atijo.
Kini iseda oro-oruko ati ona wo ni a n gba seda re?
Iseda oro-oruko je siseda oro-oruko lati ara oro-oruko tabi oro-ise nipa afomo lilo. Bi a ba fe seda oro-oruko, awon ona ti a le gba ni wonyi:
- Nipa lilo afomo ibere
- Nipa lilo afomo aarin
- Nipa sise apetunpe kikun
- Nipa sise apetunpe elebe
- Nipa sise akanpo oro-oruko
- Nipa sise isunki odidi gbolohun
Bawo ni a se n seda oro-oruko nipa lilo afomo ibere?
A le lo afomo ibere pelu oro-ise tabi lati seda oro-oruko. Iru oro-oruko bayii gbodo ni ajose pelu oro-ise ti a lo pelu afomo. Awon afomo ibere naa ni a, e, e, i, o, o, u, alai, ai, o ni, oni abbl.
Afomo ibere pelu oro-ise
| Afomo ibere | Oro | Oro-oruko ti a seda |
|---|---|---|
| a | yo | ayo |
| a | lo | alo |
| a | to | ato |
| o | ku | oku |
| o | bi | obi |
| i | to | ito |
| i | fe | ife |
| e | gbe | egbe |
| e | to | eto |
| e | te | ete |
| e | ko | eko |
| o | le | ole |
| o | mu | omu |
| i | rin | irin |
| ai | sun | aisun |
| ai | ni | aini |
| ati | lo | atilo |
| ati | je | atije |
| on | te | onte |
| alai | gbon | alaigbon |
| alai | mo | alaimo |
| oni | igi | onigi |
| oni | omo | olomo |
Afomo ibere pelu apola-ise
A le lo afomo ibere pelu apola-ise, eyi ni pe oro-ise ati oro-oruko.
| Afomo ibere | Oro-ise | Oro-oruko | Oro-oruko ti a seda |
|---|---|---|---|
| a | ko | orin | akorin |
| a | ko | ope | akope |
| a | da | ejo | adajo |
| o | da | oran | odaran |
| ati | de | ade | atidade |
| o | se | ere | osere |
| o | da | oju | odaju |
Eto iselu abinibi ni ile Yoruba
Eto iselu ni ile Yoruba bere lati inu ile. Gege bi asa, baba ni olori ile, iya ni atele, bee ni awon omo naa ni ojuse bi ojo ori won ba se telera. Eto agbo-ile ni ipile eto ijoba ni ile Yoruba.
Ipa ti baale ile, iyaale-ile, omobinrin ile, omokunrin ile ati omo osu n ko ninu eto isakoso agbo-ile ati ebi gbigboona ni a o salaye ni isalaye yii.
Baale
Olori agbo-ile ni baale. Eni ti o ba dagba ju lo ni o n je oye yii. Kii se oye ti a maa n du: ti baale kan ba ku, eni ti o ba tun dagba ju miran yoo je.
Baale ni alase ati alakooso agbo-ile. Ohun ti o ba so ni abe ge. Ko si eni ti o gbodo fi owo pa ida re loju.
Ile maa n to beere ninu agbo-ile nla, ni won a wa mo ogiri yii gbogbo ile bee ka. Ilekun kan yoo wa ni enu ona abawole tabi abajade kuro ninu agbo-ile.
Baale kii gbe eyin odi. Aarin agbo-ile ni o maa n gbe lati mojuto gbogbo ohun ti o ba n lo.
Igbejo maa n wa ti won maa n jokoo si lati gbo ejo pelu awon agbaagba bii merin. Omo kekere kan yoo maa fe abebe si baba ni ara.
Ise baale
- Ija pipari ni agbo-ile: ti ede aiyede ba waye, ise baale ni lati yanju re. Totun tosi yoo ro ejo, ki o to da ejo, baale lo maa kadii ninu ohun to ba so ni abe ge.
- Fifi omo foko: bi omobinrin ile ba fe loko, odede baale ni won yoo ti wule fun un. Bi iyawo tuntun ba si wole, o gbodo de odede baale fun adura.
- Imojuto omo ile lokunrin ati lobinrin: o gbodo mo ijade ati iwole awon odo agbo-ile.
- Ogun pipin: odede baale ni won ti n saato bi won yoo se pin ogun fun awon omo oku ni idi igi kookan.
Iyaale
Iyaale ni obinrin ti o dagba ju ni iye odun ti won wo ile oko. Oun ni igbakeji baale ninu eto iselu agbo-ile.
- O je asoju ati alamojuto awon iyawo ile ati omobinrin ile.
- Ise re ni lati mo igba ati akoko ti a bi omo lati yanju aawo ti o waye nipa ojo ori.
- Oun ni yoo toju iyawo asesegbe oyun inu, omo ikoko ati eto ila kiko fun omo tuntun.
- Iyaale gbodo ni imo kikun nipa ita idile ati oriki ile oko, yoo si maa ko awon atele re gbogbo.
Omokunrin ile
Omokunrin ile ni awon gende okunrin ti won ti laya tabi ki won je odo.
Awon ni baale maa n ran ni ise bi ile oku gbigbe, oko ile riro, ona yiye, oju ogun lilo, sisin ibi omo si baluwe abbl. Awon ni won n pa eran nibi inawo, apa eran ni won maa n fun won. Won maa n wa nibi ti baale ti n pari ija.
Obinrin ile
Obinrin ile ni iyawo agbo-ile. Ojuse won ni lati rogba yi iyaale ka, ki won si pa ofin re mo.
- Awon ni won maa n dana ounje ni akoko odun tabi ayeye.
- Awon ni won maa n sun rara nibi inawo idile oko won.
- Awon lo maa n se itoju iyawo titun ati iyawo ile to ba bimo.
- Awon lo maa n jora fun iya omo, awon lo maa n gba eyin eran.
Omo osu ile
Omo osu ile ni awon agba obinrin ti won ti losi ile oko, ti won wa pada wa maa gbe ni ile baba won. Won maa n ni enu ninu oro ebi, awon lo maa n gba aya eran ti won ba pa.
Omobinrin ile
Omobinrin ile ni awon omobinrin ti ko tii lo si ile oko. Won maa n kopa ninu oro ile. Ojuse won ni lati lo ki iyawo ile to ba bimo.
Eto iselu ode-oni
Ni aye ode-oni, eto iselu ti yato patapata si ti aye atijo.
Gomina ni olori ati alase ni ilu kookan, o si ni awon komisanna ti won jo n tuko eto ilu. Looto ni awon oba si wa, sugbon won ko ni agbara bii ti aye atijo mo.
Bee naa ni a ni awon alaga fun ijoba ibile ati awon kanselo fun agbegbe ti won n ri si idagbasoke ati ilosiwaju agbegbe won. Olori orile-ede je olori patapata fun orile-ede. Ti ohunkohun ba sele ni ipinle, olori orile-ede ni won yoo to leti.
Ti o ba je ni agbegbe tabi adugbo, kanselo a fi to alaga leti. Ti apa alaga ba ka a, yoo se e, sugbon ti o ba ju agbara re lo, o fi to gomina leti, ise naa yoo si di sise. Ti o ba ju agbara gomina lo, oun naa a fi to olori orile-ede leti.
Ajosepo to dan moran si wa laarin ijoba ode-oni pelu awon oba, nitori pe gbogbo won jo n sise po fun idagbasoke, alaafia ati ilosiwaju ilu.
Bee naa ni a ni orisiirisii awon alamojuto to n ri si oro nipa awon obinrin, odo, eto nipa oro aje, ayika, eto irinna, ina monmona, omi ero abbl.
Eto abinibi n tesiwaju ni awon igberiko wa, sugbon ko fi bee fese rinle mo bii ti aye atijo.
Fun ti idajo ni aye ode-oni, a ni ile ejo ti adajo yoo ti dajo. Bee ni awon soja, olopaa, omo ogun oju omi ati ti ofurufu fun idaabobo ilu ni aye ode-oni.
Atunyewo eko
- Fun awon oro-oruko yii ni apeere mejimeji: afoyemo, ibikan, asonka, alaisonka, aridimu.
- Ko apeere oro aropo oruko: eni kin-in-ni eyo oluwa, enikeji opo oluwa, eniketa eyo opo.
Igbelewon
- Kini iseda oro-oruko?
- Daruko ona ti a n gba seda oro-oruko.
- Salaye lori Ijoba Ibile, Ijoba Ipinle ati Ijoba Apapo.
- Seda oro-oruko mewaa nipa afomo ibere.
- Seda oro-oruko mewaa nipa afomo aarin.
- Seda oro-oruko mewaa nipa apetunpe.
Ise amurele
Apa kinni
- Aseda ife nipa lolo ____________________________
(a) afomo aarin (b) afomo ibere (d) apetunpe - Afomo ibere ninu alaigbon ni ________________
(a) ala (b) alai (d) gbon - Nje awon Yoruba gbagbo ninu iye leyin iku?
(a) rara (b) won gbagbo - Awon ___________________________ ni won maa n ku pelu oba laye atijo ki o ba le ri won ran nise ni ile ibomiran ti o ba ja si.
(a) abobaku (b) eru (d) ara ile oba - ___________________ ni a n pe eni ti o ti ku, ti o tun lo si ile ibomiran.
(a) ayorunbo (b) akudaaya (d) eni irapada
Apa keji
- Awon ona wo ni a le gba seda oro-oruko ninu ede Yoruba?
- Lo afomo ibere lati seda oro-oruko marun-un.
- Nje awon Yoruba gbagbo ninu iye leyin iku?
Iwe akatilewa
- Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3, Copromutt Publishers.
This term's Yoruba topics
SS3 Second Term · 5 topics
Get Yoruba as PDF and Word
Every week of SS3 Yoruba, Second Term, formatted and ready to print. Ad-free, and the copy lock comes off.
Get this term Card, bank transfer, USSD or OPay

