Skip to content

Atunyewo Eko Lori Asa Igbeyawo Nile Yoruba – SS3 Yoruba Lesson Note (Second Term)

Lesson note at a glance

Class
SS3
Subject
Yoruba
Term
Second Term
Reading time
6 min
Start of this note, 5 of 5
Take this term’s notes offline
Reading here is free. Download all 5 SS3 Yoruba Second term notes as PDF to print and Word to edit.
Download all three terms, ₦2,000
Instant download. Secure payment by Paystack. Card, bank transfer, USSD or OPay. Payment stuck? WhatsApp us.

Igbeyawo ni eto ti a fi n so oko ati iyawo papo.

Behavioural objectives

Ni ipari eko yii, awon akekoo yoo le:

Advertisement
  1. so awon igbese igbeyawo abinibi nile Yoruba;
  2. salaye ise ifojusode, alarina, isihun (ijohen), itoro ati idana;
  3. salaye igbeyawo soosi, igbeyawo mosalasi ati igbeyawo kootu;
  4. ko iyato laarin igbeyawo atijo ati igbeyawo ode oni.

Orisii igbeyawo wo ni o wa nile Yoruba?

Igbeyawo nile Yoruba pin si ona merin: igbeyawo atijo, igbeyawo soosi, igbeyawo mosalasi ati igbeyawo kootu.

  • Igbeyawo atijo (abinibi): eyi ti awon baba nla wa n se pelu awon igbese bi itoro, idana ati ibale.
  • Igbeyawo soosi: eyi ti awon Kristeni n se ninu ile ijosin.
  • Igbeyawo mosalasi: eyi ti awon musulumi n se.
  • Igbeyawo kootu: eyi ti a n se ni olu ile-ise ijoba ibile tabi ni kootu.

Kini awon igbese igbeyawo atijo nile Yoruba?

Igbese igbeyawo atijo nile Yoruba je mokanla: ifojusode, iwadii, alarina, isihun, itoro, baba gbo iya gbo, idana, ifa iyawo, ojo igbeyawo, ese iyawo ati ibale.

  1. Ifojusode: awon obi okunrin yoo maa fi oju sile wa obinrin.
  2. Iwadii: won yoo se iwadii idile obinrin naa ni aarin ilu, won yoo tun se iwadi lowo ifa.
  3. Alarina: eni ti won yoo maa ran si ara won (oko ati iyawo afesona). Boko ba moju aya tan, alarina a yeba.
  4. Isihun/ijohen: gbigba ti obinrin gba lati fe okunrin.
  5. Itoro: awon ebi okunrin yoo wa toro omobinrin ni owo obi re.
  6. Baba gbo, iya gbo: awon ebi mejeeji gbo, won si gba pe ki obinrin ati okunrin fera.
  7. Idana: ebi oko yoo gbe eru idana lo fun ebi omobinrin ti ojo igbeyawo won ba ku feere.
  8. Ifa iyawo: baba iyawo yoo difa ni aaro ojo igbeyawo lati mo ile oko naa yoo se ri, boya yoo san sowo somo.
  9. Ojo igbeyawo: ale ni awon ebi ati ore iyawo yoo ba a palemo.
  10. Ese iyawo: ni enu ona abawole won yoo fi omi we ese iyawo naa.
  11. Ibale: ti iyawo ko ba ti i mo okunrin kan ri, ti oko re ba a nile, oko yoo gbe ekun agbe emu tabi ile isana kikun ranse si obi iyawo pelu owo ibale.
Advertisement

Kini ise alarina ninu eto igbeyawo atijo?

Alarina ni eni ti won n ran si oko ati iyawo afesona gege bi onise.

  • Ise re: o n gbe oro laarin oko ati iyawo afesona.
  • Igba ti ise re pari: boko ba moju aya tan, alarina a yeba.

Kini iyato laarin itoro ati idana?

Itoro ni igba ti ebi okunrin wa toro omobinrin lowo obi re. Idana ni eru ti ebi oko gbe lo fun ebi omobinrin ki ojo igbeyawo to de.

Koko Itoro Idana
Ohun ti o je Bibere omobinrin lowo obi re. Gbigbe eru lo fun ebi omobinrin.
Ti o se e Awon ebi okunrin. Ebi oko.
Akoko Ni ibere, leyin ti omobinrin ti gba (isihun). Ti ojo igbeyawo ba ku feere.
Awon ohun ti a n lo Ko si eru kan pato ti a daruko ninu eko yii. Isu ogoji, orogbo ogoji, obi ogoji.

Bawo ni igbeyawo ode oni se ri?

Igbeyawo ode oni wa ni ona meta: soosi, mosalasi ati kootu. Orisirisii ona ni a n gba gbe iyawo lode oni.

Kini igbeyawo soosi?

Igbeyawo soosi ni eyi to maa n waye laarin awon elesin Kristeni ninu ile ijosin won.

  • Ibi ti o ti waye: ninu ile ijosin (ile Olorun).
  • Kikede: won yoo kede eni to ba ri idi ti won ko fi le so oko ati iyawo papo ko tete wa so bee.
  • Eni ti o ba ni atako: bi ko ba so nigba naa, ko gbe enu re dake laelae.
  • Ibere eto: bi won ko ba ri enikeni ti o yoju ni won to le so awon mejeeji po.
  • Iyawo: ko faye gba ju iyawo kan lo.

Kini igbeyawo mosalasi?

Igbeyawo mosalasi ni eyi to maa n waye laarin awon musulumi.

  • Iyawo: o faye gba ju iyawo kan lo, nitori won ni “me” ni Olorun wi, ti agbara eniyan ba ti kaa.
  • Iyawo saara: awon musulumi a maa fi omo se saara lai je pe onitohuni fi okan sii tele.
  • Itumo saara: ki won fun eniyan ni iyawo lairo tele (iyawo ofe). Eyi ni won n pe ni iyawo saara.
Advertisement

Kini igbeyawo kootu?

Igbeyawo kootu ni igbeyawo alarede ti awon loko laya n se ni olu ile-ise ijoba ibile tabi ni kootu.

  • Ibi ti a ti n se e: olu ile-ise ijoba ibile tabi kootu.
  • Iwe ase: awon oko ati iyawo yoo fowo si iwe ase lodo ijoba.
  • Oruka: won a si gba oruka arede.
  • Iyawo: ko faye gba ju iyawo kan ati oko kan lo.

Bawo ni igbeyawo ode oni se ba asa Yoruba mu?

Igbeyawo ode oni fese mule daadaa nile Yoruba nitori esin igbagbo ati Isilamu to fese mule lode oni.

  • Awon ilana atijo: gbogbo ilana lati ibi itoro titi de idana maa n saba je eyi ti a n tele.
  • Ekun iyawo: ko si ohun to n je ekun iyawo mo ni aye ode oni.
  • Iwa awon wundia: opolopo awon wundia iwoyi ni won ti daju, gbogbo won ni oju n kan lati lo ile oko.
  • Iwo ile oko: ko si ohun to fe pawon lekun nitori won ko ka ile oko si ohun babara.

Kini iyato laarin igbeyawo atijo ati igbeyawo ode oni?

Igbeyawo atijo ni eyi ti a n se nipa asa abinibi Yoruba. Igbeyawo ode oni ni eyi ti a n se nipa esin (soosi ati mosalasi) tabi nipa ofin ijoba (kootu).

Koko Igbeyawo atijo Igbeyawo ode oni
Ipile re Asa abinibi Yoruba. Esin Igbagbo, Isilamu tabi ofin ijoba.
Iwadii A n wadii idile ati lowo ifa. Ko je ohun ti a daruko ninu eko yii.
Iwe ati oruka Eru idana ni won n gbe lo. Igbeyawo kootu n lo iwe ase ati oruka arede.
Iyawo Ibale ati ese iyawo wa ninu eto re. Soosi ati kootu faye gba iyawo kan nikan, mosalasi faye gba ju kan lo.
Ekun iyawo Iyawo n sunkun nigba ti o n lo ile oko. Ko si ohun to n je ekun iyawo mo.
Advertisement

Evaluation

  1. Ki ni a n pe ni ifojusode ninu eto igbeyawo abinibi?
  2. Se alaye ise alarina.
  3. Kini ijohen tabi isihun tumo si?
  4. Kini iyato laarin itoro ati idana?
  5. Ko iyato meta laarin igbeyawo aye ode oni ati aye atijo.

Assignment

Ise asetilewa

  1. Awon ………….. lo n se igbeyawo soosi. (a) Musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa
  2. Awon ………………………… lo n se igbeyawo mosalasi. (a) Musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa
  3. Awon …………………………… lo maa fi omo se saara. (a) Onigbagbo (b) Alarede (d) Musulumi
  4. Awon to maa n fe iyawo ju eyo kan lo lode oni ni (a) musulumi (b) soosi (d) kootu.
  5. ‘Titi iku yoo fi ya won’ inu irufe igbeyawo aye ode oni wo ni eyi je mo? (a) musulumi (b) soosi (d) kootu.

Apa keji

  1. Kini a n pe ni idana ninu eto igbeyawo nile Yoruba?
  2. Kini ijohen, lati odo tani ijohen ti n wa?

This term's Yoruba topics

SS3 Second Term · 5 topics

  1. Atunyewo Eko Lori Silebu Ede Yoruba, Elegbejegbe Tabi Irosiro
  2. Fonoloji Ede Yoruba, Agbeyewo Awon Orisa Ile Yoruba
  3. Atunyewo Eko Lori Oro-Ayalo, Eto Ebi Ati Iserun Eni
  4. Iseda Oro-Oruko, Eto Iselu Abinbi Ati Ti Ode-Oni
  5. Atunyewo Eko Lori Asa Igbeyawo Nile Yoruba
Advertisement

Lesson Notes for Other Classes

Print it or edit it in Word

Every note is free to read online. A PDF or Word copy of one subject costs ₦1,000 for one term, or ₦2,000 for all three terms.

Sign in first, then choose your class and subject at checkout.