Skip to content

Atunyewo Eko Lori Silebu Ede Yoruba, Elegbejegbe Tabi Irosiro – SS3 Yoruba Lesson Note (Second Term)

Download this term · ₦1,000

Lesson note at a glance

Subject
Yoruba
Class
SS3
Term
Second Term
Topic
Atunyewo Eko Lori Silebu Ede Yoruba, Elegbejegbe Tabi Irosiro
Order
Topic 1 of 5 this term
Reading time
5 min

Silebu ni ege oro ti o kere ju ti eemi le gbe jade leekan soso. Silebu kookan ni odo silebu, eyi ti o maa n dun ju, o si le ni apaala silebu, ti o je konsonanti. Elegbejegbe si ni egbe ti awon odo ati agba da sile ni agbegbe won fun igbega ilu ati ara won.

Advertisement

Afojusun eko

Ni opin eko yii, awon akekoo yoo le:

  • salaye silebu ki won si pin oro si silebu;
  • salaye odo silebu ati apaala silebu pelu apeere;
  • salaye ihun silebu [F, KF ati N] ninu oro olopo silebu;
  • salaye elegbejegbe, daruko apeere won ki won si so iwulo won;
  • daruko awon koko ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti ijoba ya.

Ede: silebu ede Yoruba

Kin ni silebu?

Silebu ni ege oro ti o kere ju ti eemi le gbe jade leekan soso. Apeere:

Oro Pipin si silebu Iye silebu
Ajayi A-ja-yi meta
Olabisi O-la-bi-si merin
Adeleke A-de-le-ke merin
Olopaa O-lo-pa-a merin
Gbangbadekun gba-n-gba-de-kun marun-un

Kin ni odo silebu?

Odo silebu ni apa ti o se pataki julo ninu ihun silebu kookan. Iro faweli ati iro konsonanti aranmupe asesilebu ni o maa n sise gege bi odo silebu.

  • Odo silebu ni o maa n dun ju ninu silebu.
  • Awon iro odo silebu ni a maa n gbo ju ninu oro.
  • Ori odo silebu ni a maa n fi ami ohun si.
  • Kan-an-n-pa ni odo silebu je ninu ihun silebu.

Apeere: wa, gba, sun

Kin ni apaala silebu?

Apaala silebu je iro konsonanti yato si konsonanti aranmupe asesilebu [m, n]. Iru iro bee ni o maa n sise gege bi apaala silebu.

Apeere: gbo, dun, ko, we

Bawo ni ihun silebu [F, KF ati N] se ri ninu oro olopo silebu?

Orisiirisii ona ni a le gba se ihunpo silebu ninu oro olopo silebu.

Oro Ihun Iye silebu
Aso A / so
F / KF
2
Bata ba / ta
KF / KF
2
Igbale i / gba / le
F / KF / KF
3
Alupupu A / lu / pu / pu
F / KF / KF / KF
4
Konko ko / N / ko
KF / N / KF
3

Iwe akatilewa

Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3. Copromutt Publishers.

Asa: elegbejegbe oriki orisii ipa ti won n ko ni awujo

Kin ni elegbejegbe?

Elegbejegbe ni egbe ti awon odo ati agba, ni okunrin tabi ni obinrin, ti won je iro da sile ni agbegbe won fun igbega ilu ati ara won.

Advertisement

Ni aye atijo, iwonba ni ise ti ijoba maa n se fun awon ara ilu. Igbega ati idagbasoke ilu tabi igberiko maa n waye pelu iranlowo awon elegbejegbe wonyi. Apeere iru egbe bee ni aye atijo ni egbe ogboni.

Apapo awon agba ilu ti won to omo bii aadota odun ni won maa n wo egbe ogboni. Ojuse egbe ogboni ni lati fun oba ni imoran. Won ni agbara lati da oba lekun tabi le oba kuro lori ite ti o ba si agbara lo.

Awon elegbejegbe ode-oni

Ni ode-oni, awon elegbejegbe po jantirere. Apeere won ni:

  • Lion’s club
  • Rotary club
  • Majeeobaje
  • Oredegbe ati bee bee lo.

Ni ilu tabi ileto ti awon egbe wonyi ba wa, orisiirisii ise idagbasoke ni won maa n se, bii:

  • tite tabi titun afara se;
  • kiko ile ero kaakiri ibudoko.

Kin ni iwulo elegbejegbe?

  1. Awon egbe ogboni maa n kopa ninu eto iselu awon baba-nla wa.
  2. Won maa n kopa ninu ise bii: ona yiye, afara odo titun se, aafin oba kiko.
  3. Won maa n kopa ninu pipese owo ajemonu fun awon akekoo ile-iwe giga, pipese eko ofe fun awon akekoo ile-iwe girama, sisan owo idanwo iwe mewaa.
  4. Aaro kikojo, owe bibe, eesu kikojo fun iranlowo egbe ati enikookan omo egbe.

Litireso: ogbon itopinpin litireso

Eyi ni awon koko to se pataki ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti ijoba ya eyi ti a maa ka. Oun akoko ti a gbodo mo ni oruko iwe, oruko onkowe, ibudo itan, itan ni soki, awon eda itan, ona isowolo-ede, eko ti a ri ko, asa Yoruba ati beebee lo.

Iwe ti a maa gbe yewo ni OMO TI A TI A FI ISE WO ati ORE MI.

Oruko onkowe

Oruko awon onkowe iwe naa ni: Ojukorola O. ati Aderibigbe M.

Ibudo itan

Ibudo itan n’ toka si ilu ti itan inu iwe yii ti waye. Awon ilu ti itan naa ti waye ni:

Advertisement

Akanlo ede ayaworan

Owe, akanlo ede, afiwe, awitunwi, asorege, ifohunpeniyan, iforodara abbl.

Iwe akatilewa

Simplified Yoruba ati litireso

Igbelewon

Igbelewon lori silebu

  1. Kin ni silebu?
  2. Salaye ihun silebu pelu apeere.
  3. Pin awon oro yii si silebu:
    • Agbalagbaakan
    • Olowolayemo
    • Gbangbalakoogbo
    • Oji ku tu ba-ra orunsaaro
    • Operekete

Igbelewon lori odo silebu ati apaala silebu

  1. Salaye ni ekunrere lori odo silebu ati apaala silebu pelu apeere.
  2. Eya ihun silebu meloo ni o wa? Fi apeere gbe idahun re lese.
  3. Ki ni pataki konsonanti aranmupe n ati m ninu ege silebu?

Igbelewon lori elegbejegbe

  1. Nje egbejegbe ni anfaani kankan ninu asa Yoruba bi? Se alaye kikun.
  2. Daruko egbejegbe ibile Yoruba marun-un ti o mo.

Atunyewo eko

  1. Salaye iro konsonanti.
  2. Salaye iro faweli.

Ise asetilewa

Awon ibeere olopo yiyan

  1. ……… ni ege oro ti eni lo gba jade leekansoso. (a) oro (b) apola (d) silebu
  2. ……… ni a n lo fun idagbasoke ilu. (a) iro (b) egbe (d) aaro
  3. ……… ni maa n gbo ju ninu silebu. (a) odo silebu (b) ihun silebu (d) apaala silebu
  4. ……… ki i se ara erongba elegbejegbe. (a) ona yiye (b) afara tite (d) aibowofagba
  5. Apeere elegbejegbe laye atijo ni ……… (a) egbe onimototo (b) egbe ogboni (d) Rotary

Theory

  1. (a) Ki ni silebu? (b) Salaye ihun silebu pelu apeere.
  2. Kin ni odo ati apaala silebu? Fi idahun re han pelu apeere.
  3. (a) Kin ni elegbejegbe? (b) Salaye iwulo elegbejegbe merin ti o mo.

This term's Yoruba topics

SS3 Second Term · 5 topics

  1. Atunyewo Eko Lori Silebu Ede Yoruba, Elegbejegbe Tabi Irosiro
  2. Fonoloji Ede Yoruba, Agbeyewo Awon Orisa Ile Yoruba
  3. Atunyewo Eko Lori Oro-Ayalo, Eto Ebi Ati Iserun Eni
  4. Iseda Oro-Oruko, Eto Iselu Abinbi Ati Ti Ode-Oni
  5. Atunyewo Eko Lori Asa Igbeyawo Nile Yoruba
Downloads

Get Yoruba as PDF and Word

Every week of SS3 Yoruba, Second Term, formatted and ready to print. Ad-free, and the copy lock comes off.

Get this term Card, bank transfer, USSD or OPay

Advertisement

Lesson Notes for Other Classes

Print it or edit it in Word

Every note is free to read online. A PDF or Word copy of one subject costs ₦1,000 for one term, or ₦2,000 for all three terms.

Continue with GoogleContinue with Facebook

Sign in first, then choose your class and subject at checkout.