Atunyewo Eko Lori Oro-Ayalo, Eto Ebi Ati Iserun Eni – SS3 Yoruba Lesson Note (Second Term)
Download this term · ₦1,000Lesson note at a glance
- Subject
- Yoruba
- Class
- SS3
- Term
- Second Term
- Topic
- Atunyewo Eko Lori Oro-Ayalo, Eto Ebi Ati Iserun Eni
- Order
- Topic 3 of 5 this term
- Reading time
- 8 min
Oro-ayalo ni oro ti a mu lati inu ede kan wo inu ede miiran lona ti pipe ati kiko re yoo fi wa ni ibamu pelu ede ti a mu-un wo. Yoruba n ya oro lati inu ede Geesi, Larubawa ati Faranse nipase ilana afetiya ati ilana afojuya. Oro-ayalo maa n mu ki ede dagba.
Behavioural objectives (Ibi ti eko yii pari si)
Ni opin eko yii, awon akekoo yoo le:
- so kini oro-ayalo je ati inu awon ede ti a ti n ya oro wonu ede Yoruba;
- salaye ilana afetiya ati ilana afojuya pelu apeere;
- so awon ona ti oro-ayalo gba wonu ede Yoruba;
- salaye awon ofin ede Yoruba ti oro-ayalo gbodo tele;
- salaye itumo iserun eni ati igba ati ohun ti a fi n bo won;
- salaye eto ebi ati awon ibasepo ti o wa ninu ebi.
Kini oro-ayalo?
Oro-ayalo ni awon oro ajeji ti a maa n ya wonu ede Yoruba lati inu ede miiran.
Oro-ayalo ni mimu oro lati inu ede kan wo inu ede miiran lona ti pipe ati kiko re yoo fi wa ni ibamu pelu ede ti a mu-un wo.
Oro-ayalo maa n mu ki ede dagba. Bakan naa, o maa n je ki oruko wa fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba n sese n wo awujo wa.
Inu awon ede wo ni a ti n ya oro wonu ede Yoruba?
Inu awon ede wonyii ni a ti n ya oro wo inu ede Yoruba:
- Ede Geesi
- Ede Larubawa
- Ede Faranse
Ona wo ni a n gba ya oro wonu ede Yoruba?
Yoruba ni ilana meji ti won n gba ya oro wo inu ede Yoruba, awon naa ni:
- Ilana afetiya
- Ilana afojuya
Ilana afetiya
Eyi ni pipe oro-ayalo ni ona to sunmo bi awon elede se n pe oro gan-an.
| Oro-ayalo | Ede Yoruba |
|---|---|
| Bible | Baibu |
| Peter | Pita |
| Table | Tebu |
| Esther | Esita |
| Deacon | Dikin |
| Council | Kansu |
| Al-basal | Alubosa |
Ilana afojuya
Eyi ni kiko oro ni ilana eyi to sunmo bi awon elede se n ko. Awon elede saaba maa n lo ilana yii.
| Oro-ayalo | Ede Yoruba |
|---|---|
| Soldier | Soja |
| Table | Tabili |
| Peter | Peteru |
| Esther | Esiteri |
| Bible | Bibeli |
| Deacon | Diakoni |
| Paradise | Paradise |
| Hebrew | Heberu |
Bawo ni oro-ayalo se wonu ede Yoruba?
Eyi ni orisirisii ona ti oro-ayalo gba wonu ede Yoruba:
- Esin: nipase esin musulumi ati esin Kristi ti won mu wa fun wa ni a se ni awon oro wonyi: mosalasi, soosi, alijanna, angeli, bibeli, pasito, kurani abbl.
- Ajose owo: eyi ni ajose owo laarin Yoruba ati awon eya miiran, ap: senji, korensi, wisiki, buluu.
- Eto iselu: nipase ijoba ajeji ti awon Larubawa ati Geesi mu wa ni a ti ya opolopo oro bii seria, kootu, sinato.
- Asa ati olaju: ajumose nipa asa ati olaju mu ki a ya opolopo oro lo, ap: yigi, mared.
- Eto eko: eyi ni oro ti a ya nipa eto eko, ap: tisa, boodu.
Awon iro ti a fi n se aaro ara won
Ki oro ede Geesi ti a ya lo to le di ara oro ede Yoruba, o gbodo tele ofin ede Yoruba.
1. Fifi faweli seyin oro
Konsonanti ki i gbeyin oro ninu ede Yoruba. Bi oro-ayalo ba ni, a o fi faweli ti o ye seyin re. O le je: i, u, a tabi o, ap.
| Ede Geesi | Ede Yoruba |
|---|---|
| Bread | buredi |
| Gum | goomu |
| Bed | beedi |
| Shirt | seeti |
| Fail | feeli |
| Glass | gilaasi |
| Gold | goolu |
2. Yiyo konsonanti ipari oro-ayalo kuro
| Ede Geesi | Ede Yoruba |
|---|---|
| Mobil | mobi |
| Moses | mose |
| Jesus | jesu |
| Lazarus | lasaru |
3. Yiya isupo konsonanti
Isupo konsonanti oro-ayalo ni a maa n fi faweli ya, ap.
| Ede Geesi | Ede Yoruba |
|---|---|
| Bread | buredi |
| Milk | miliiki |
| Iray | Tiree |
| Station | Tesan |
| Belt | beliiti |
4. Ifiropo konsonanti
Nigba miiran, konsonanti oro Geesi maa n yato si ti Yoruba, ap:
| Ede Geesi | Ede Yoruba |
|---|---|
| Lazarus | lasaru |
| Church | soosi |
| Queen | kun-yin |
| Valve | faafu |
| Stamp | sitanbu |
| Cup | koobu |
Ofin ati iwulo oro-ayalo
Ofin ti o de oro-ayalo
- Ami gbodo wa lori oro-ayalo.
- Oro-ayalo lo maa n bere pelu ami ohun oke.
- Faweli aranmupe maa n bere oro-ayalo.
Iwulo oro-ayalo
- Oro-ayalo lo maa n mu ki ede dagba.
- Nipa yiya oro lo a maa n ri oruko fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba sese n wo awujo wa.
Igbelewon
- Kin ni oro-ayalo?
- Ona meloo ni a n gba lati ya oro lo? Salaye won pelu apeere.
Asa: awon iserun eni
Kini iserun eni?
Awon iserun eni tumo si baba-nla eni, ti o se iran eni sile tabi ori eni ti iran kan ti bere. Ko si iran kan ni ile Yoruba ti ko ni awon ti o see nitori pe ‘okun ki i gun titi ki o ma ni ibi ti o ti fa wa’.
Awon baba-nla wa ti a n toka si yii ti wa nigba iwase, won ti se gudugudu meje ohun yaaya mefa nigba aye won.
Awon Yoruba gbagbo pe odo ki san ki o gbagbe orisun re. Opolopo igba ni won maa n pe oruko baba-nla fun iyonu ati aabo, nitori pe won gbagbo pe eni to ba ti ku ni agbara nla lati bukun awon ti won je iran won ni aye.
Igba ati ona ti a n gba bo iserun eni
Akoko odun tabi loorekoore ni a maa n se etutu lati tu awon iserun eni loju fun oore ti won n reti lodo won. Odoodun ni awon iran miiran maa n bo iserun won, tabi nigba ti wahala tabi idarudapo ba wa ninu ebi won.
Ebi kookan ni o ni ojubo ti won ti n bo iserun won. O le je agboole tabi ni eyin odi ilu. Iru eyin odi yii le je ibi ti baba-nla won tedo si nigba iwase. Ogangan ibi ti oku ba kori si ni won ti n se etutu.
Orisiirisii ohun jije mimu ni won n bo iserun eni, agbo tabi agutan, adie abbl. Won yoo si ro eje re si oju oori iserun won naa, won yoo da obi. Ti o ba si ti yan, o ti gba niyen. Akoko ayeye ni o maa n je fun gbogbo ebi.
Ni ile Ijebu, Agemo ni won n se. Awon ni ipinle Eko kii fi Adamu-Orisa sere.
Bawo ni a se n da iserun eni mo?
Ila oju, oriki-orile ati isesi iran kookan je eyi ti a fi n da ara wa mo, ti o si n mu iserun eni wa si iranti. Inu oriki-orile ise, ise, iwa, esin ati eewo iran ni a ti n gbo oniruuru oruko ti awon baba-nla wa ti je seyin.
Apeere:
- Iran Onikoyi je iran jagun, eyi si han ninu oriki ati itan iran won. Baba-nla won je jagunjagun.
- Iwa akin hihu ko si fi iran yii sile.
- Iran Aagberi ko fe gbagbe oogun abenu gongo.
- Iran Olofa kan o je gbagbe ijakadi.
Igbelewon
- Ki ni iserun eni tumo si?
- Daruko awon iserun ile Yoruba ti o mo.
Asa: eto ebi
Kini eto ebi?
Ni ile Yoruba, ebi ni a tun n pe ni alajobi tabi molebi. Alajobi ni iya, baba, egbon, aburo ati ibatan eni ni apapo. Eto ebi ni opomulero ti o gbe asa, ise ati ibara-eni-gbepo awon Yoruba duro. Omo nibi-niran ni awon Yoruba. Bi won se tan si ile baba ni won tan si ile iya.
Eto ebi bere lati inu ile. Gege bi asa, baba ni olori ile, iya ni atele ki o kan awon omo gege bi ojo ori won. Iko kokan ni o ni ipa ti o n ko lati mu ki ife, isokan, laafia ati ajosepo wa ninu ebi.
Awon ibasepo ti o wa ninu ebi
- Ise obi si omo
- Ise omo si obi
- Ibasepo laarin omo iya si omo iya
- Ibasepo laarin Obakan si Obakan
- Ibasepo laarin idile eni ati baba eni
- Ipo Baale ati ojuse re
- Ipo Iyaale ile ati ise re
- Ipo Obinrin ile
- Ipo Orogun
- Ipo Omo osu ati ise won
- Ipo Omokunrin ile ati ise won
- Ipo Omobinrin ile
- Awon Alejo tabi Alabagbe
Igbelewon
- Salaye awon wonyi: Obakan, Iyekan-eni, Omo osu, Obinrin ile ati Omobinrin ile.
- Ki ni ojuse Baale ile? Salaye ni kikun.
Litireso
Kika iwe ti ajo WAEC yan.
Igbelewon
- Kin ni iserun eni?
- Igba wo ni a n bo iserun eni?
- Kin ni a fi n bo won?
Evaluation (Apapo igbelewon)
- Kin ni oro-ayalo?
- Ona meloo ni a n gba lati ya oro lo? Salaye won pelu apeere.
- Salaye awon wonyi: Obakan, Iyekan-eni, Omo osu, Obinrin ile ati Omobinrin ile.
- Ki ni ojuse Baale ile? Salaye ni kikun.
Atunyewo eko
- Ki ni oro oruko?
- Ki ni oro aropo oruko?
- Ko iyato merin laarin oro oruko ati oro aropo oruko.
Assignment (Ise asetilewa)
Apa kinni
- Awon iserun eni tumo si (a) Baba-nla eni (b) eni ti o se iran eni sile (d) eni to na omokunrin ile.
- Inu _______ ni a ti n gbo nipa oniruuru oruko idile. (a) oriki orile (b) iwure (d) ofo
- Ojubo iserun eni le wa ni _____ ati (a) inu ile (b) agboole (d) ilu odikeji.
- Ona _____________ ni a le gba ya oro lo ninu ede Yoruba. (a) meji (b) meta (d) merin
- A ya pasito ni pase _____. (a) esin (b) eto eko (d) imo ero
Apa keji
- Kin ni oro-ayalo?
- Ona meloo ni a n gba ya oro wonu ede Yoruba?
- Ko irisi awon oro Geesi wonyi sile leyin igba ti a ba ti ya won wonu ede Yoruba: Teacher, Starch, Milk, bread, class, scale, block, trouser, brother, shilling.
- Kin ni iserun eni?
- Daruko apeere iserun eni meta ni ile Yoruba.
- Daruko igba ati ohun ti a si n bo iserun eni.
- Salaye eto ebi ni kikun.
Iwe akatilewa
- Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3. Copromutt Publishers.
- Imo Ede Asa ati Litireso Yoruba (SS3), S.Y Adewoyin, oju-iwe 277 si 279.
This term's Yoruba topics
SS3 Second Term · 5 topics
- Atunyewo Eko Lori Silebu Ede Yoruba, Elegbejegbe Tabi Irosiro
- Fonoloji Ede Yoruba, Agbeyewo Awon Orisa Ile Yoruba
- Atunyewo Eko Lori Oro-Ayalo, Eto Ebi Ati Iserun Eni
- Iseda Oro-Oruko, Eto Iselu Abinbi Ati Ti Ode-Oni
- Atunyewo Eko Lori Asa Igbeyawo Nile Yoruba
Get Yoruba as PDF and Word
Every week of SS3 Yoruba, Second Term, formatted and ready to print. Ad-free, and the copy lock comes off.
Get this term Card, bank transfer, USSD or OPay

