Fonoloji Ede Yoruba, Agbeyewo Awon Orisa Ile Yoruba – SS3 Yoruba Lesson Note (Second Term)
Download this term · ₦1,000Lesson note at a glance
- Subject
- Yoruba
- Class
- SS3
- Term
- Second Term
- Topic
- Fonoloji Ede Yoruba, Agbeyewo Awon Orisa Ile Yoruba
- Order
- Topic 2 of 5 this term
- Reading time
- 6 min
Foniimu ni awon iro ti o le fi iyato han laaarin oro kan tabi omiran. Bi a ba fi iro kan dipo ikeji ninu oro, iyato yoo wa ninu oro naa. Foniimu ede Yoruba pin si ona meta: foniimu konsonanti, foniimu faweli ati foniimu ohun.
Behavioural objectives
By the end of the lesson, students should be able to:
- define foniimu and eda foniimu;
- name the three types of foniimu in Yoruba (konsonanti, faweli and ohun) and give examples;
- name the three toniimu (oke, isale and aarin);
- state the two names of Obatala and what he is known for;
- explain the difference between Orunmila and Ifa.
Ki ni foniimu?
Foniimu ni awon iro ti o le fi iyato han laaarin oro kan tabi omiran. Foniimu ni /b/ /d/ /t/, eyi ti o tumo si pe bi a ba fi iro kan dipo ikeji iyato yoo wa.
Apeere:
- Ede
- Ere
- Epe
- Ege
- Egbe
Idako foonu faweli: a {a}
Baba ko ebe: {baba k כ ebe}
Ona wo ni foniimu ede Yoruba pin si?
Foniimu ede Yoruba pin si ona meta:
- Foniimu konsonanti
- Foniimu faweli
- Foniimu ohun
Foniimu konsonanti
Iro aseyato ni gbogbo iro konsonanti ede Yoruba fere je. Apeere: ba, pa, wa.
/b/ ni eda {b}, to je konsonanti akunyun afeji ete, pe asenupe. O le jeyo nibi gbogbo, apeere bo /b כ/ [b כ].
Foniimu faweli
Foniimu faweli naa je iro aseyato. Bi a ba fi faweli kan ropo ikeji, iyato yoo wa ninu oro naa. Apeere: Wa, Wo, We.
Foniimu faweli pin si ona meji:
- Faweli airanmupe
- Faweli aranmupe
Apejuwe foniimu faweli: /a/ ni eda [a], ayanupe, aarin, perese. O maa n jeyo nibi gbogbo, apeere s /Sa/ [Sa] ati apa /akpa/ [akpa].
Kini foniimu ohun?
Iro ohun a maa je foniimu tabi toniimu. Eyi ni pe ohun ori silebu kan le mu ki oro kan yato si ikeji paapaa ninu ede olohun bii ede Yoruba.
Foniimu ohun pin si ona meta:
- Toniimu oke: / | / apeere Ja
- Toniimu isale: | \ | apeere iwa
- Toniimu aarin
Apeere:
- wi
- wa
- so
- igba (re re)
- igba (garden egg)
- igba (time)
- igba (calabash)
Ki ni eda foniimu?
Eda foniimu ni awon iro ti ko le fi iyato han laarin itumo oro kan ati omiran. Eda foniimu je ifonka alaiseyato ninu ede Yoruba.
Apeere eda foniimu faweli ni \ I/ ati / n/. Eyi ni pe bi a ba fi won ropo ara won ninu oro, ko ni si iyato.
Apeere:
- ni aya ati laya
- ni ana ati l anaa
- mo ni aso ati mo laso
- Ogunbambo ati Ogunbanbo
- Oronbo ati Orombo
O kan je eda ikeji, bee ni ko si iyato kankan laarin won.
Eda faweli: eda faweli foniimu faweli ede Yoruba ni / a / an ati כ// on.
Apeere:
- Itan / Iton
- Iran / Iren
- Okan / Okon
Obatala
Itan so nipa Obatala wi pe oun ni ipo re ga julo ninu gbogbo orisa. Oun ni o lagbara julo ninu won, oun si ni asaaju won patapata. Oruko meji ni a le pe orisa yii nile Yoruba. A le pe e ni Obatala, eyi ti o ja si ‘Oba ti ala’, a tun le pe e ni Orisa-nla, eyi ti o ja si ‘Oba ti-o-nla’, Oba ti o tobi.
Oun kan naa ni a gbo pe o je igba keji Eledaa Olodumare. O di igba keji nitori pe oun gan-an ni Eledaa koko da. Leyin eyi ni Eledaa fun un ni agbara lati ran oun lowo ninu ise re gege bi Eledaa. A gbo pe Obatala ni i se oju, imu, enu, eti ati awon eya ara yooku leyin ti Eledaa ba ti da ara borogidi tan.
Awon aro, amunkun, afin, abuke, afoju ati awon miiran bee la n pe ni ‘eni orisa’. Awon wonyi ni Obatala fi ise tabi owo agbara re han. A si tun n pe e ni ‘Alamo Rere’ nitori pe o ni anfaani lati lo amo re fun siseda eniyan. Igbagbo awon olorisa Obatala nipe bi Olodumare ba se ara tan, yoo fi ara naa ranse si Obatala ki o tan eda naa wa si aye, ti yoo si maa so titi ojo aye re.
Obatala ko fe epo, osun bi ko se ala. Aso funfun ni awon aworo Obatala ati awon olusin re maa n lo ni ojo odun re. Iyan ati obe funfun ni ti Obatala, inu igba funfun ni a o de iyan re si. Obe ti a fi eran igbin ati ori se ni ti Obatala.
Aso funfun, gele funfun ati ileke ni iyawo Obatala maa n lo ni ojo odun re.
Ta ni Orunmila, ki ni Ifa?
Nigba ti a ba daruko Ifa, okan opolopo eniyan ni o maa n lo si odo Orunmila. Looto ni Orunmila je baba Ifa, sugbon kii se oun nikan ni Ifa ti a n da nile Yoruba.
Ipo Ifa ni aye atijo
Ni aye atijo, ko si ohunkohun ti a le se nile Yoruba lailo beere lodo Ifa. Ti a ba fe fe iyawo, a o lo beere boya wundia ti okan wa so ni yoo je iyawo rere abi bee ko. Bi a ba bimo, a nilati lo beere esentaye omo lodo Ifa abbl.
Awon ohun ti a n se nile Yoruba ti a kii fi ti Ifa si ko wopo. Owo Ifa ni a ti n beere eni ti o maa je Oba, ohun ni o mo eni ti yoo yooku ni aarin ilu. Paripari re ni wi pe owo Ifa ni a ti beere ojo ti o ba to ti o si ye lati bo Ifa ni odun. Eleyi fi han kedere lori ipo ti awon Yoruba fi Ifa si.
Yato si Orunmila, awon Ifa miiran ti o wa ni ile Yoruba ni Agbigba, Obi, Ile, Olokun, Olokun-awo, Wo-mi-pee.
Orunmila
Awon onitan so fun wa pe Orunmila ni eni naa ti Olodumare ran lati wa se igba keji re ni aye. Odo re ni a o ti maa beere orisii nnkan nitori o je eni ti o gbon lopolopo. Awon tile so pe o wa nibe nigba ti Olodumare da gbogbo ohun ti o n be ninu aye pelu eniyan, paapaa idi re e ti a fi n pe e ni Eleri-ipin.
Apeja oruko Orunmila ni ‘Orun-mo-eni-ti-o-maa-la’. Itan kan so wipe o ni baba ati iya, sugbon won ko gbe ile aye pelu re. Esanyin je oluranlowo pataki fun Orunmila.
Ekuro ni Ifa ti o je irinse fun Orunmila. Awon babalawo ni o je aworo Orunmila tabi Ifa.
Litireso
- Kika iwe ti ijoba yan
Iwe itokasi
- Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3. Copromutt Publishers.
- Olu, D. ati Jeje, A. (1970) AWON ASA ATI ORISA ILE YORUBA. Onibonoje Press.
- Imo Ede Asa ati Litreso Yoruba SS3. S.Y Ademoyin o.i 83 si 90.
Igbelewon
- Ki ni foniimu? Salaye ni ekunrere.
- Ki ni eda foniimu? Salaye ni ekunrere.
- Fun fonoloji ni oriki.
- Ona meloo ni foniimu pin si?
- Salaye orisa Orunmila.
- Salaye iyato ti o wa laarin Orunmila ati Ifa.
- Se agekuru ohun ti e ka ninu iwe adakedajo.
- Ko iyato merin laarin iro konsonanti ati iro faweli sile.
Ise asetilewa
Apa kinni
- Foniimu ni _______ (a) iro ti a pe (b) to le fi iyato han (d) iro ti o dun
- Faweli pin si ona ____ (a) meji (b) meta (d) merin
- Iro ______ naa ni a mo si toniimu (a) faweli (b) konsonanti (d) ohun
- Eda foniimu konsonanti ni _______ (a) /b/ ati /d/ (b) /i/ ati m (d) /I/ ati /n/
- Idako ‘on’ ni _____ (a) /on/ (b) /c/ (d) /כ/
Apa keji
- Pelu apeere, salaye iyato to wa laarin iro foniimu ati eda foniimu.
- Se adako foonu fun awon faweli ti a fala si nidi ninu awon oro wonyi: Imu, Won, Yen, Esin, Aso, Eyele ati Sola lo si ile ijosin.
- Salaye iyato ti o wa laarin Obatala ati Orunmila.
This term's Yoruba topics
SS3 Second Term · 5 topics
- Atunyewo Eko Lori Silebu Ede Yoruba, Elegbejegbe Tabi Irosiro
- Fonoloji Ede Yoruba, Agbeyewo Awon Orisa Ile Yoruba
- Atunyewo Eko Lori Oro-Ayalo, Eto Ebi Ati Iserun Eni
- Iseda Oro-Oruko, Eto Iselu Abinbi Ati Ti Ode-Oni
- Atunyewo Eko Lori Asa Igbeyawo Nile Yoruba
Get Yoruba as PDF and Word
Every week of SS3 Yoruba, Second Term, formatted and ready to print. Ad-free, and the copy lock comes off.
Get this term Card, bank transfer, USSD or OPay

