Skip to content

Atunyewo Eko Lori Asa Igbeyawo Nile Yoruba – SS3 Yoruba Lesson Note (Second Term)

Download this term · ₦1,000

Lesson note at a glance

Subject
Yoruba
Class
SS3
Term
Second Term
Topic
Atunyewo Eko Lori Asa Igbeyawo Nile Yoruba
Order
Topic 5 of 5 this term
Reading time
4 min

Igbeyawo ni eto ti a fi n so oko ati iyawo papo. Nile Yoruba, asa igbeyawo atijo ni igbese bi ifojusode, iwadii, alarina, isihun, itoro, idana, ifa iyawo, ojo igbeyawo, ese iyawo ati ibale. Lode oni, igbeyawo soosi, mosalasi ati kootu ni a n se, won si yato si ti atijo.

Advertisement

Behavioural objectives

Ni ipari eko yii, awon akekoo yoo le:

  • so awon igbese igbeyawo abinibi nile Yoruba;
  • salaye ise ifojusode, alarina, isihun (ijohen), itoro ati idana;
  • salaye igbeyawo soosi, igbeyawo mosalasi ati igbeyawo kootu;
  • ko iyato laarin igbeyawo atijo ati igbeyawo ode oni.

Bawo ni asa igbeyawo atijo (ibile) nile Yoruba se n lo?

Tabili yii fi awon igbese igbeyawo atijo ati alaye won han.

Igbese igbeyawo Alaye
Ifojusode Awon obi okunrin yoo maa fi oju sile wa obinrin.
Iwadii Won yoo se iwadii idile obinrin naa ni aarin ilu. Won yoo tun se iwadi lowo ifa.
Alarina Alarina ni won yoo maa ran si ara won (oko ati iyawo afesona). Boko ba moju aya tan, alarina a yeba.
Isihun/ijohen Gbigba ti obinrin gba lati fe okunrin.
Itoro Awon ebi okunrin yoo wa toro omobinrin ni owo obi re.
Baba gbo, iya gbo Awon ebi mejeeji gbo, won si gba pe ki obinrin ati okunrin fera.
Idana Ebi oko yoo gbe eru idana lo fun ebi omobinrin ti ojo igbeyawo won ba ku feere. Isu ogoji, orogbo ogoji, obi ogoji.
Ifa iyawo Baba iyawo yoo difa ni aaro ojo igbeyawo lati mo ile oko naa yoo se ri boya yoo san sowo somo.
Ojo igbeyawo Ale ni awon ebi ati ore iyawo yoo ba a palemo, won yoo sin iyawo lo si ile oko pelu orin ati ijo titi yoo fi de enu ona oko re.
Ese iyawo Ni enu ona abawole won yoo fi omi we ese iyawo naa.
Ibale Ti iyawo ko ba ti i mo okunrin kan ri, ti oko re ba a nile, oko yoo gbe ekun agbe emu tabi ile isana kikun ranse si obi iyawo pelu owo ibale.

Bawo ni igbeyawo ode oni se ri?

Lode oni, aye ti di amulumala. Orisirisii ona ni a n gba gbe iyawo. A n gbe iyawo ni ile Olorun, a n gbe e ni kootu, a si n gbe ni mosalasi. Igbeyawo soosi yii fese mule laarin awon onigbagbo, igbeyawo mosalasi si mule laarin awon musulumi.

Advertisement

Igbeyawo soosi

Igbeyawo soosi ni eyi to maa n waye laarin awon elesin Kristeni ninu ile ijosin won. Ki eto igbeyawo yii to waye, won yoo ti maa kede eni to ba ri idi ti won ko le fi so oko ati iyawo naa papo ko tete wa so bi bee ko, ki eni be gbe enu re dake laelae. Bi won ko ba ti ri enikeni ko yoju ni won to le so awon mejeeji po. Iru igbeyawo yii ko faye gba ju iyawo kan lo.

Igbeyawo mosalasi

Igbeyawo mosalasi maa n waye laarin awon musulumi. Eyi faye gba ju iyawo kan lo nitori won ni “me” ni Olorun wi, ti agbara eniyan ba ti kaa.

Awon musulumi a maa fi omo se saara lai je pe onitohuni fi okan sii tele. Eyi ni pe ki won fun eniyan ni iyawo lairo tele (ki won fun eeyan ni iyawo ofe). Eyi ni won naa n pe ni iyawo saara.

Igbeyawo kootu

Awon loko laya miiran a ma n se igbeyawo alarede. Won a lo si olu ile-ise ijoba ibile tabi kootu lati fowo si iwe ase lodo ijoba, won a si fi bee gba oruka arede. Eleyii naa ko faye gba ju iyawo kan ati oko kan lo. Igbeyawo kootu ni a n pe e.

Igbeyawo ode oni ati asa Yoruba

Orisii igbeyawo yii fese mule daadaa nile Yoruba nitori esin igbagbo ati Isilamu to fese mule lode oni. Gbogbo ilana lati ibi itoro titi de idana maa n saba je eyi ti a n tele.

Ni aye ode oni ko si ohun to n je ekun iyawo mo. Opolopo awon wundia iwoyi ni won ti daju, gbogbo won ni oju n kan lati lo ile oko. Ko tile sohun to fe pawon lekun nitori won ko ka ile oko si ohun babara.

Advertisement

Evaluation

Igbelewon lori asa igbeyawo atijo

  1. Ki ni a n pe ni ifojusode ninu eto igbeyawo abinibi?
  2. Se alaye ise alarina.
  3. Kini ijohen tabi isihun tumo si?
  4. Kini iyato laarin itoro ati idana?

Apapo igbelewon

  1. Salaye lori igbeyawo aye ode oni.
  2. Ko iyato meta laarin igbeyawo aye ode oni ati aye atijo.
  3. Salaye lori ise ode.

Assignment

Ise asetilewa

  1. Awon ………….. lo n se igbeyawo soosi. (a) Musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa
  2. Awon ………………………… lo n se igbeyawo mosalasi. (a) Musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa
  3. Awon …………………………… lo maa fi omo se saara. (a) Onigbagbo (b) Alarede (d) Musulumi
  4. Awon to maa n fe iyawo ju eyo kan lo lode oni ni (a) musulumi (b) soosi (d) kootu.
  5. ‘Titi iku yoo fi ya won’ inu irufe igbeyawo aye ode oni wo ni eyi je mo? (a) musulumi (b) soosi (d) kootu.

Apa keji

  1. Kini a n pe ni idana ninu eto igbeyawo nile Yoruba?
  2. Kini ijohen, lati odo tani ijohen ti n wa?

This term's Yoruba topics

SS3 Second Term · 5 topics

  1. Atunyewo Eko Lori Silebu Ede Yoruba, Elegbejegbe Tabi Irosiro
  2. Fonoloji Ede Yoruba, Agbeyewo Awon Orisa Ile Yoruba
  3. Atunyewo Eko Lori Oro-Ayalo, Eto Ebi Ati Iserun Eni
  4. Iseda Oro-Oruko, Eto Iselu Abinbi Ati Ti Ode-Oni
  5. Atunyewo Eko Lori Asa Igbeyawo Nile Yoruba
Downloads

Get Yoruba as PDF and Word

Every week of SS3 Yoruba, Second Term, formatted and ready to print. Ad-free, and the copy lock comes off.

Get this term Card, bank transfer, USSD or OPay

Advertisement

Lesson Notes for Other Classes

Print it or edit it in Word

Every note is free to read online. A PDF or Word copy of one subject costs ₦1,000 for one term, or ₦2,000 for all three terms.

Continue with GoogleContinue with Facebook

Sign in first, then choose your class and subject at checkout.