Atunyewo Eko Lori Asa Igbeyawo Nile Yoruba SS3 Yoruba Lesson Note

Download Lesson Note
Lesson Notes

Topic: Atunyewo Eko Lori Asa Igbeyawo Nile Yoruba

AKOONU

  • IFOJUSODE
  • ALARINA                                                   
  • IJOHEN/ISIHUN
  • ITOORO
  • IDANA

ASA IGBEYAWO ATIJO (IBILE)

IGBESE IGBEYAWO                             ALAYE

Ifojusode: Awon obi okunrin yoo maa fi oju sile wa obinrin.

Iwadii: Won yoo se iwadii idile obinrin naa ni aarin ilu. Won yoo tun se, iwadi lowo ifa.

Alarina: Alarina ni won yoo maa ran si ara won (oko ati  Iyawo                                   afesona), Boko ba moju aya tan, alarina a yeba.

Isihun/ijohen: Gbigba ti obinrin gba lati fe okunrin.

Itoro: Awon ebi okunrin yoo wa toro omobinrin ni owo obi re.

Baba gbo, iya: Awon ebi mejeeji gbo, won si gba pe ki obinrin ati okunrin fera 

Idana : Ebi oko yoo gbe eru idana lo fun ebi omobinrin ti ojo igbeyawo won ba ku feere. Isu ogoji, orogbo ogoji, obi ogoji.

Ifa iyawo: Baba iyawo yoo difa ni aaro ojo igbeyawo lati mo ile oko naa yoo se ri boya yoo san sowo somo.

Ojo igbeyawo: Ale ni awon ebi ati ore iyawo yoo ba a palemo, won yoo sin iyawo lo si ile oko pelu orin ati ijo titi yoo fi de enu ona oko re.

Ese iyawo: Ni enu ona abawole won yoo fi omi we ese iyawo naa.

Ibale: Ti iyawo ko ba ti i mo okunrin kan ri, ti oko re ba a nile, oko yoo gbe ekun agbe emu tabi ile isana kikun ranse si obi iyawo pelu owo ibale. 

 

IGBELEWON

  1. Ki ni a n pe ni ifojusode ninu eto igbeyawo abinibi
  2. Se alaye ise alarena
  3. Kini ijohen tabi isihun tumo si?
  4. Kini iyato laarin itoro ati idana?

 

IGBEYAWO ODE ONI                                                                                

AKOONU:-

  • IGBEYAWO SOOSI
  • IGBEYAWO MOSOLASI
  • IGBEYAWO KOOTU

Lode oni, aye ti di amulumala. Orisirisii ona ni a n gba gbe iyawo.  A n gbe iyawo ni ile Olorun, a n gbe e ni kootu, a si n gbe ni mosalasi.  Igbeyawo soosi yii fese mule laarin awon onigbagbo, igbeyawo mosalasi si mule laarin awon musulumi.

Igbeyawo soosi ni eyi to maa n waye laarin awon elesin Kristeni ninu ile ijosin won, sugbon ki eto igbeyawo yii to waye ni won yoo ti maa kede eni to ba ri idi ti won ko le fi so oko ati iyawo naa papo ko tete wa so bi bee ko, ki eni be gbe enu re dake laelae.  Bi won ko ba tiri enikeni ko yoju ni won to le so awon mejeeji po.  Iru igbeyawo yii ko faye gba ju iyawo kan lo. 

Igbeyawo mosolasi maa n waye laarin awon musulumi, eyi faye gba ju iyawo kan lo nitori won  ni “me” ni Olorun wi, ti agbara eniyan ba ti kaa.  Awon musulumi a maa fi omo se saara lai je pe onitohuni fi okan sii tele eyi ni pe ki won fun eniyan ni iyawo lairo tele (ki won fun eeyan ni iyawo ofe).  Eyi ni won naa n pe ni iyawo saara. 

Orisii igbeyawo yii fese mule daadaa nile Yoruba nitori esin igbagbo ati Isilamu to fese mule lode oni.  Gbogbo ilana lati ibi itoro titi de idana maa n saba je eyi ti a n tele. 

Awon loko laya miiran a ma n se igbeyawo alarede ti o je pe won a lo si olu ile-ise ijoba ibile tabi Kootu lati fowo si iwe ase lodo ijoba, won a si fi bee gba oruka arede.  Eleyii naa ko faye gba ju iyawo kan ati oko kan lo.Igbeyawo kootu ni a n pe e. 

Ni aye ode oni ko si ohun to n je ekun iyawo mo, opolopo awon wundia iwoyi ni won ti daju, gbogbo won ni oju n kan lati lo ile oko.  Ko tile sohun to fe pawon lekun nitori won ko ka ile oko si ohun babara. 

APAPO IGBELEWON

  1. Salaye lori igbeyawo aye ode oni
  2. Ko iyato meta laarin igbeyawo aye ode oni ati aye atijo.
  3. Salaye lori ise ode

ISE ASETILEWA

  1. Awon………….. lo n se igbeyawo soosi (a) Musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa.
  2. Awon …………………………lo n se igbeyawo Mosolasi (a) musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisi
  3. Awon ……………………………lo maa fi omo se saara (a) Onigbagbo (b) Alarede (d) Musulumi 
  4. Awon to maa n fe iyawo ju eyo kan lo lode oni ni (a) musulumi (b) soosi (d)  kootu
  5. ‘titi iku yoo fi ya won’ inu inu irufe igbeyawo aye ode oni wo ni eyi je mo?. (a) musulumi (b) soosi (d)  kootu. 

APA KEJI

  1. Kini a n pe ni idana ninu eto igbeyawo nile Yoruba
  2. Kini ijohen, lati odo tani ijohen ti n wa?

 

Lesson Notes for Other Classes