Iseda Oro-Oruko, Eto Iselu Abinbi Ati Ti Ode-Oni SS3 Yoruba Lesson Note
Download Lesson NoteTopic: Iseda Oro-Oruko, Eto Iselu Abinbi Ati Ti Ode-Oni
ISEDA ORO-ORUKO
IHUN ORO (ISODORUKO)
IGBESE
Bi a se n seda oro oruko nipa lilo afomo ibere
AKOONU:-
Iseda oro-oruko je siseda oro-oruko lati ara oro-oruko tabi oro-ise nipa afomo lilo. Bi a ba fe seda oro oruko eyi ni awon igbese ti a ni lati tele.
- Nipa lilo afomo ibere
Nipa lilo afomo aarin
Nipa sise apetunpe kikun
Nipa sise apetunpe elebe
Nipa sise akanpo oro-oruko
Nipa sise isunki odidi gbolohun
- Lilo afomo ibere
A le lo afomo ibere pelu oro-ise tabi lati seda oro-oruko. Iru oro-oruko bayii gbodo ni ajose pelu oro ise ti a lo pelu afomo. Awon afomo ibere naa ni a, e, e, i o o u, alai, ai, o ni, oni abbl.
Apeere
a + yo = ayo
a + lo = alo
a + to = ato
o + ku = oku
o + bi = obi
i + to = ito
i + fe = ife
e + gbe = egbe
e + to = eto
e + te = ete
e + ko = eko
o + le = ole
o + mu = omu
i + rin = irin
ai + sun = aisun
ai + ni = aini
ati + lo = atilo
ati + je = atije
on + te = onte
alai + gbon = alaigbon
alai + mo = alaimo
oni + igi = onigi
oni + omo = olomo
- A le lo afomo ibere pelu apola-ise eyi ni pe oro-ise ati oro-oruko
Apeere
a + ko + orin = akorin
a + ko + ope = akope
a + da + ejo = adajo
o + da + oran = odaran
ati + de + ade = atidade
o + se + ere = osere
o + da + oju = odaju
IGBELEWON
Kin ni iseda oro-oruko?
Daruko ona ti a n gba seda oro- oruko
IWE AKATILEWA
- Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA J. S.S.3 Copromutt Publishers.
Asa
ETO ISELU ABINIBI ATI ODE ONI
Ipa ti baale ile, Iyaale-ile omobinrin ile, omokunrin ile, omo osu n ko ninu eto isakoso agbo ile ati ebi gbigboona.
Eto iselu ni ile Yoruba bere lati inu ile, gege bi asa ,baba ni Olori ile, iya ni atele bee ni awon omo naa ni ojuse bi ojo ori won ba se telera.
Eto agbo-ile ni ipile eto ijoba ni ile Yoruba. Olori agbo-ile ni
Baale: ni eni ti o ba dagba ju lo ni o n je oye yii. Kii se oye ti a maa n du, ti bale kan ba ku ni eni ti o ba tun dagba ju miran yoo je.
Baale ni alase ati alakooso agbo ile, Ohun ti o ba so ni abe ge. Ko si eni ti o gbodo fi owo pa ida re loju.
Ile maa n to beere ninu agbo ile nla ni won a wa mo ogiri yii gbogbo ile bee ka, ilekun kan yoo wa ni enu ona abawole tabi abajade kuro ninu agbo ile.
Baale kii gbe eyin odi, aarin agbo – ile ni o maa n gbe lati mojuto gbogbo ohun ti o ba n lo.
Igbejo maa n wa ti won maa n jokoo si lati gbo ejo pelu awon agbaagba bii merin. Omo kekere kan yoo maa fe abebe si baba ni ara.
ISE Baale
Ija pipari ni agbo-ile: ti ede aiyede ba waye ise baale ni lati yanju re. Totun tosi yoo ro ejo, ki in to da ejo, bale lo maa kadii ninu ohun to ba si so ni abe ge.
Fifi omo foko: bi omobinrin ile bafe loko, odede bale ni won yoo ti wule fun-un. Bi iyawo tuntun ba si wole o gbodo de odede baale fun adura.
Imojuto omo ile lokunrin ati lobinrin o gbodo mo Ijade at iwole awon odo agbo ile.
Ogun pipin: Odede baale ni won ti n saato bi won yoo se pin ogun fun awon omo oku ni idi igi kookan.
Iyaale: ni Obinrin ti o dagba ju ni iye odun ti won wo ile oko. Oun ni igbakeji bale ninu eto iselu agbo ile.
O je asoju ati alamojuto awon iyawo ile ati omobinrin ile.
Ise re ni lati mo igba ati akoko ti a bi omo lati yanju aawo ti o waye nipa ojo ori.
Oun ni yoo toju iyawo asesegbe oyun inu, omo ikoko ati eto ila kiko fun omo tuntun.
Iyaale gbodo ni imo kikun nipa ita idile, oriki ile oko, ti yoo si maa ko awon atele re gbogbo.
Omokunrin Ile: ni awon gende okunrin ti won ti laya tabi ki won je odo.
Awon ni bale maa n ran ni ise bi ile oku gbigbe, oko ile riro, ona yiye, oju ogun lilo sisin ibi omo si baluwe abbl awon ni won n pa eran nibi inawo apa eran ni won maa n fun won. Won maa n wa nibi ti bale ti n pari ija.
Obinrin ile,! Awon ni iyawo agbo-ile, ojuse won ni lati rogba yi iyaale ka, ki won sa pa ofin re mo.
Awon ni won maa n dana ounje ni akoko odun tabi ayeye. Awon ni won maa n sun rara nibi inawo idile oko won.
Awon lo maa n se itoju iyawo titun ati iyawo ile to ba bimo. Awon lo maa n jora fun iya omoawon lo maa n gba eyin eran.
Omo osu Ile -: ni awon agba obinrin ti won ti losi ile oko, ti won wa pada wa maa gbe ni ile baba won.
Won maa n ni enu ninu oro ebi, awon lo maa n gba aya eran ti won ba pa.
Omobinrin ile-: ni awon omobinrin ti ko tii lo si ile oko. Won maa n kopa ninu oro ile
Ojuse won ni lati lo ki iyaawo ile to ba bimo.
IGBELEWON
- Salaye lori Ijoba Ibile Ijoba Ipinle ati Ijoba Apapo.
ETO ISELU ODE-ONI
Ni aye ode-oni eto iselu ti yato patapata is ti aye atijo.
Ni aye ode-oni, eto iselu ti aye ode-oni ni a n lo gomina ni Olori ati alase ni ilu kookan ti o si ni awon komisanna ti won jo n tuko eto ilu. Loooto ni awon oba si wa sugbon won ko ni agbara bii ti aye atijo mo
Bee naa ni a ni awon alaga fun ijoba ibile ati awon Kanselo fun agbegbe ti won n ri si idagbasoke ilosiwaju agbegbe won nigbat ti olori orile –ede je olori patapata fun orile-ede, ti ohunkohun ba sele ni ipinle Olori-onle-ede ni won yoo ti to leti, ti o ba si je ni agbegbe tabi adugbo ni kaunselo a fi to alaga leti, ti apa alaga ba kaa yoo see sugbon ti o ba ju agbara re lo, o fi to gomina leti ise naa yoo si di sise.
Ti o ba ju agbara gomina lo, oun naa a fi to Olori Orile-ede leti
Ajosepo to dan moran si wa laarin ijoba ode-oni pelu awon oba nitori pe gbogbo won jo n sise po fun idagbasoke, alaafia ati ilosiwaju ilu ni.
Bee naa ni a ni Orisiirisii awon alamojuto to n ri si or nipa awon obinrin, odo eto nipa oro aje, ayika, eto irinna, ina monmona abbl. Omi ero.
Eto abinibi is n tesiwaju ni awon igberiko wa sugbon ko fi bee fese rinle mo bii ti aye atijo.
Fun tie to idajo-ni aye ode oni a ni ile ejo ni ti adajo yoo ti dajo bee ni awon soja, Olopaa, Omo ogun oju omi ati ti ofurufu fun idaabobo ilu in aye ode-oni.
IGBELEWON
- Salaye lori Ijoba Ibile Ijoba Ipinle ati Ijoba Apapo.
APAPO IGBELEWO
- Seda oro oruko 10 nipa: afomo ibere.
- Seda oro oruko 10 nipa afomo aarin
- Seda oro oruko 10 nipa apetunpe.
ATUNYEWO EKO
- Fun awon oro oruko yii ni apeere mejimeji: afoyemo, ibikan, asonka, alaisonka. Aridimu.
- ko apeere oro aropo oruko: eni kin-in-ni eyo oluwa. Enikeji opo oluwa, eniketa eyo opo.
IWE AKATILEWA
- Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.
ISE AMURELE
- Aseda ife nipa lolo ____________________________
(a) afomo aarin (b) afomo ibere (d) apetunpe
- Afomo ibere ninu alaigbon ni ________________
(a) ala (b) alai (d) gbon
- Nje awon Yoruba gbagbo ninu iye leyin iku
(a) rara (b) won gbagbo
- Awon ___________________________ni won maa n ku pelu Oba laye atijo ki o ba le ri won ran nise ni ile ibomiran ti o ba ja si.
(a) Abobaku (b) eru (d) ara ile oba
- ___________________ni a n pe eni ti o ti ku, ti o tun lo si ile ibomiran
(a) ayorunbo (b) Akudaaya (d) eni irapada
APA KEJI
- Awon ona wo ni a le gba seda oro-oruko ninu ede Yoruba?
- Lo afomo ibere lati seda oro-oruko marun-un
- Nje awon Yoruba gbagbo ninu iye leyin iku